Alaga fẹgbẹ oṣelu NDC nipinlẹ Ogun, Fẹmi Alao, ti sọ pe iṣẹ pataki to wa niwaju wọn ti wọn ba wọle ibo lọdun 2027, ni lati kọkọ wa ọna abayọ sawọn aṣiṣe tijọba to wa lode nipinlẹ naa ti ṣe.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ilu ko fararọ, ebi n pa awọn araalu, wọn ko jẹ ki wọn ni irọrun, ọpọ ileri ti wọn si ṣe nigba ti wọn fẹẹ gbajọba lo jẹ ofo.
Nitori idi eyi lawọn araalu fi n fojoojumọ darapọ mọ ẹgbẹ NDC bayii tawa naa ko si nii jawọn nitanmọ.
Ọkunrin naa sọrọ yii nibi ifọrọwerọ kan to waye laipẹ yii nibi to ti mẹnuba igbaradi wọn fun ibo to n bọ lọna naa.
O sọ pe "Ẹgbẹ tuntun ni a le pe NDC tẹlẹ nipinlẹ Ogun, amọ ni bayii, ki i ṣe bẹẹ mọ, Nitori bi oṣu meloo kan ṣẹyin lawọn eeyan gbọ hulẹhulẹ nipa ẹ.
"Amọ bi oṣu kan si akoko yii ariwo okiki ẹgbẹ ọhun ti tan kalẹ, o ti di eyi to n bawọn to wa nibẹ lakooko yii dije fawọn ipo kaakiri. O ti gbooro bẹẹ lo tun ti gbilẹ nipinlẹ Ogun.
Nipa aṣeyọri ti wọn ti ni latigba ti wọn ti da a silẹ nipinlẹ Ogun, o sọ pe, "Awọn aṣeyọri to maa n de ba ẹgbẹ ni taa ba n ri awọn eeyan lọtun losi lati wọọdu titi de ipinlẹ, ti wọn wa n darapọ aṣeyọri to lagbara ni.
"Nitori pe awa gan an ko mọ pe a le gbilẹ to bayii, to fi di pe ojoojumọ la n gboro si.Lati bi oṣu meji sẹyin ni ṣa a n gba ipe tawọn eeyan fifẹ han lati darapọ mọ NDC.
"Igba ti Obi ati Kwankwaso ti de ni ẹgbẹ naa ti gbilẹ gan an ni.Mo si le fọwọ sọya pe ẹgbẹ oṣelu NDC ti n bo orukọ ẹgbẹ kan to ti wa nilẹ tẹlẹ lọ nipinlẹ Ogun".
Bẹẹ lo tun, "Ẹgbẹ wa ti wa nimurasilẹ fun ibo to n bọ lọdun 2027. Laipẹ yii la ṣe ipade gbogboogbo fawọn oloye ẹgbẹ lati wọọdu de ipinlẹ.
"Lẹyin naa la a ṣe ibo alabẹsekele iyẹn pamari fawọn to fẹẹ dije dupo fun ibo to n bọ lọna naa. Koda awọn ajọ eleto idibo iyẹn INEC ni wọn wa salamojuto.
"Mo fẹẹ mu da yin loju pe gbogbo awọn oludije wa lati ọmọ ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, Aṣoju- ṣofin, ọmọ ile igbimọ aṣofin tipinlẹ to fi dori gomina ni wọn wẹ ja kainkain ti wọn kun oju oṣuwọn.
"Awọn ibi kan wa tawọn oludije jọ ja dupo ṣugbọn ti wọn yanju ẹ laarin ara wọn, ki ẹ le mọ bi ẹgbẹ wa ṣe lagbara to.
"Nipinlẹ Ogun, awọn araalu ti ṣetan lati yan olori tuntun, koda ipinlẹ yii nikan kọ, ni orileede lapapọ.
"Kin ni idi?Ijọba elebi la wa ninu ẹ, nitori pe ibo to gbe wọn wọle ohun ti wọn fi kede fawọn araalu ni pe awọn maa ṣe igba, awọn yoo ṣe awo, to jẹ pe otubantẹ ni.
"Ẹ woo, eto aabo wa lakooko yii, awọn ileri ofo, ti wọn ko mu ṣẹ fawọn araalu. Gbogbo ẹ lawọn eeyan ti ri pe ijọba to wa nilẹ irọ pọju.
Ebi n pa awọn eeyan, ilu ko rọgbọ, oore ọfẹ lawa eeyan fi wa laye. Ẹ tun wo awọn ọmọleewe ti wọn ti ji ko latọjọ.
"Aarẹ wa Tinubu, awọn eeyan roo pe yoo le ṣe ni, gbogbo wa nigbagbọ pe o le ṣe nitori ọpọ rii gẹgẹ bi ẹni ti oye ijọba tiwa-n-tiwa ye, to ti ṣe NADECO ati gbogbo ẹ, nigba to de bẹ, ofo ni.Latigba to ti de bẹ ilu ko rọgbọ, Ọlọrun ni ko ṣaanu wa.
"Nipa eto aabo, ki i ṣe ipinlẹ Ogun nikan, lorileede ni papọ, ohun to ba ti ba oju, o ti ba imu. Ko rọgbọ, ko dara, a ko faramọ.
"A fi kawọn olori to wa nibẹ ṣatunṣe, a n ṣe oṣelu, ko yẹ ka fọmọ, ara wa, ẹmi wa ṣe, ẹ wo awon ọmọleewe atawọn olukọ wọn ti wọn mu bi oṣu meji, a fi ki Ọlọrun ṣaanu.
Ki Ọlọrun da si ọrọ orileede lati gba wa lọwọ awọn aninilara to wa nijọba.
O tun sọ pe, "Gẹgẹ bi alaga fẹgbẹ oṣelu NDC nipinlẹ Ogun, a ni awọn eto ti yoo mu irọrun, atunṣe, ilọsiwaju ati idagbasoke wa.
"Ṣe ẹ mọ pe ẹgbẹ tuntun ni, aṣiṣe tawọn to wa nijọba ti ṣe, ni awa yoo wa atunṣe si. A ni eto fun gbogbo araalu, igba ti wa maa yatọ.
"Ohun ti mo ri lara Peter Obi ti mo fi tẹle gẹgẹ bi aarẹ orileede yii, o jẹ ẹni ti ko nimọ tara ẹni, ko si ẹgbẹ oṣelu to lọ tawọn eeyan ko ni sọ pe awọn ko nii mu.
"lṣejọba ẹ yatọ nigba to fi jẹ gomina, ko ṣejọba apo ara ẹ, lakooko naa bawọn kan ṣe si ọfiisi fun Iyawo wọn, ko ṣe e ni tiẹ.
"Bi ẹẹmẹta ọtọọtọ ni mo ti ba a pade ninu baalu, ko bawọn fi owo Ijọba ṣofo, o ni iwa ọmọluabi lara. Idi niyii tawọn araalu fi n fẹ ko di aarẹ.
"Ẹru Ọlọrun ba mi gan an ni, nitori latigba to ti denu ẹgbẹ yii, ojoojumọ lawọn eeyan n darapọ. Ti wọn n pe mi nipinlẹ Ogun, nitori wọn ti ri iwa ọmọluabi lara ẹ. Wọn ti rii gẹgẹ bi ẹni to le tun orileede yii ṣe.
"Ki a maa gbowo lọjọ idibo, ki n ṣe nnkan to tọna, nibi taa ba ara wa lorileede yii niyẹn. Ko sẹni ti wọn ba fun lowo ti ko nii gba, ko sẹni ti ko fẹran owo.
A ni ki wọn ma gba owo, ṣugbọn ẹ dibo fun ẹri ọkan yin, ẹni ti ẹ mọ pe yoo tun ilu ṣe ti yoo mu irọrun ba yin".

No comments:
Post a Comment