IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Wednesday, 19 July 2023

Aralola gbe Oruko Naijiria ga laarin awon oyinbo- Ni gbogbo won ba n pariwo pe Idan gangan ree o


Ti won ba so pe idan gangan, ko selomi-in ti won n so to ju asaaju awon obinrin onilu, Arabinrin Serifat Olamuyiwa ti gbogbo aye mo si Aralola lo. Idi nipe arewa obinrin naa ti fi Ilu ati orin dara laarin awon oyinbo alawo funfun.
 Se Lawon oyinbo ati dudu la enu sile ti won ko le e pa a de, nigbati won ri ara nla ti Aralola filu da lara, ni gbogbo won ba n pariwo pe idan gangan ree o, won lawon ko ri iru idan ti Ara pa yii latojo tawon ti date.

Gege bi a se gbo, orileede Spain lohun-un ni Aralola ti gboruko orileede yii ga, ti obinrin naa je kawon dudu ati oyinbo mo pe Olorun jogun ebun nla fun Iran Yoruba. Lara awon ayeye ti won se ni Spain ti Aralola ti dabira ni: Fuertventuraenmusica festival, Etnosur festival 
Imaginafunk festival 
Folkdelmundo festival 
CanariasJazz festival 
Canariasjazz festival 
Sinsal festival atawon mi-in
Awon ilu ti Aralola ti fakoyo ni:Fuertventura, Grand CanariaJaen,Algaceria,Granada

Nitori itu meje di ode n pa ninu igbo ti Aralola pa yii, lawon eeyan kan fi so pe ebun ti awon eeyan wa ni Naijiria ko mo iyi e ni awon oyinbo gbe osuba randerande fun yii, won ni iyi ati aponle ti ko si fun ebun wa la a se padanu ebun nla bii Sade Adu ati Asa sowo awon oyinbo.

 Ju gbogbo e lo, awon oyinbo ti so pe Aralola lo ye ki won maa pe ni idan gangan.

No comments:

Post a Comment

Adbox