Bakan naa ni won so pe ooto, iwa omoluabi, ifarajin, ife araalu ati afojusun rere ti ileese Adron ni lo so o di asiwaju laarin awon yooku.
Siwaju si i, ileese Adron wa a benu atelu iroyin eleje ati ofege tawon kan n gbe kiri ori ero ayelujara pe ileese naa lu awon onibaara re ni jibiti nipa gbigba owo lowo won la I fun won nile won, won ni iro funfun balau, to jina sooto ni eyii.
Ninu oro ileese Adron ni won tun ti so pe awon eleetanu ti won n fi gbogbo ojo ati asiko won wa isubu ileese naa ni won so pe ileese Adron fi dandan le e pe awon enjinnia won lo gbodo ba awon to ra ile lowo won ko ile won, won ni eyi ko ri bee nitori pe pupo ninu awon to ra ile lowo awon ni won ko ile won funra won.
Bee ni won salaye siwaju si i pe anfaani wa fun enikeni lati wadii ohun ti ko ba ye e lowo ileese Adron dipo iroyin ti ko lese nle ti won n gbe e kiri igboro.
Lakotan, Adron ni awon ko ni i kaare lati ri i pe gbogbo eeyan lo di onile lori pelu irorun nitori pe igbe aye ifokanbale awon omo orileede yii lo je ileese Adron logun ju.

No comments:
Post a Comment