IROYIN YAJOYAJO

ipolowo

Friday, 19 October 2018

WAHALA WA O: WON FEE FORUKO ESTHER IGBEKELE LU AWON ARAALU NI JIBITI

Image may contain: 1 person, smiling, close-upGbajugbaja olorin emi nni, Ajiyinrere Esther Igbekele tawon eeyan mo si Duchess of music ti ke gbajare sita pe awon eeyan kan fee foruko oun lu awon to fee lo siluu oyinbo ni jibiti owo nla.

Image may contain: 1 person
FOTO ATORUKO TAWON ONIJIBITI NAA LO NIYII
Ninu alaye ti osere tawon eeyan feran daadaa yii se lo ti so pe awon onijibiti gbe foto ati oruko oun sori ero ayelujara ti won so pe kawon to ba fee lo siluu oyinbo tete mu owo wa koun si mu won lo la i si wahala kankan.

O ni, Esther Haruna lonijibiti naa pe oruko ara re, to si lo okan ninu awon foto oun lati je kawon ti won fee lu ni jibiti yii ro pe oun gan-an leni to fee ko won lo siluu oyinbo yii.

Esther waa ro awon araalu lati ma fun enikan kan lowo loruko oun pelu erongba pe oun yoo mu won lo siluu oyinbo.  
'Mo be yin, e ma fun enikan kan lowo loruko mi pe mo fee gbe yin lo siluu oyinbo, emi ki i ko eeyan lo siluu oyinbo, orin nikan ni mo mo on ko lo ni temi, e sora fawon onijibiti o'.    

No comments:

Post a Comment

Adbox